Nitorina bayi ni ki enyin ma gbadura: Baba wa ti mbe li orun; Ki a bowo fun oruko re. Ki ijoba re de; Ife tire ni ki a se, bi ti orun, beni li aiye. Fun wa li onje ojo wa loni. Dari gbese wa ji wa, bi awa ti ndariji awon onigbese wa. Ma si fa wa sinu idewo, sugbon gba wa lowo bilisi. Nitori ijoba ni tire, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.